Yoruba Love Text Messages
in

Yoruba Love Text Messages with English Translations (2024)

Matters of the heart are complex, who can delve into it? Love is beautiful. Love is the most powerful force on earth, more powerful than money. Love intoxicates. It can level mountains of difficulties. Love brings unspeakable joy and can undo a terrible wrong. No one is by any means immune to romantic expressions of love.

Oro Ife, bi adanwo ni. Ife l’oni agbara ju n’ile aye. Ohun ti owo s’etì, bíntín ni l’oju Ife. Ife otito kii s’ètàn. Ife a ma pani bi otí. O si le so oke isoro di pètélè. Ife a ma mu inu eni dun, a si ma tun nkan to ti baje se.

Love is more powerful than any destructive force and is more effective than a healing draught/pill. A love between a man and a woman is unsearchable, a riddle, an enigma.

Ife l’ágbára ju gbogbo egbogi oloro to le ba nkan je lo. O si tun l’ágbára ju egbogi iwosan amúnilára dá lo.
Ife laarin okunrin ati obinrin ko se túwò, awamaridi ni.

One can’t be in love without expressing it to the object of your affection. Anyone who is smitten by love must express it verbally and non verbally at all times. This constant verbal expression of love keeps the flame alive. It is impossible to switch on a lantern without fuelling it to get brightness.

Eniyan kii nyofe ko gbenu dáké, o ma ntu jade bi ogidi emu ni. Eni ti o feran arabinrin tabi arakunrin re, ni lati ma s’ofun l’óòrèkóòrè. Eyi ni ko ni jeki ina Ife ku. Ko sese k’a tan atupa, k’a ma ro epo si ti aba fe ko tan ‘na kedere laiku.

For the fire of love to burn brightly without flickering out, it’s essential you express your feelings to your girlfriend or boyfriend. Tell him/her how much you care. The more you express your love, the merrier and the more electrifying your relationship will be.

Ki ina ife le jòó lai si ìrèwèsì, dandan ni ki o so fun ololufe re, eni bi okan re bi o se nse o. Bi ife re se ri ni ookan àyà re. “Mo ti with fun l’ana/l’enu ojo meta yi, ko si ninu oro ife. Bi ololufe meji ba nsoro ife, a ma fè si, kè si, a si ma je ki okan won fa si ara won.

Telling the love of your life you adore him or her will spice up your relationship. He/She will respond in kind. In fact, it’s the surest way of nipping off a lovers’ tiff. It guarantees a renewed and appreciable progress in your love relationship. Nothing can quench the fire of your love.

Ti o ba so fun ololufe re bi o se feran e si, inu re yoo dun, ori re too wu. Kódà, ti o ba mbínu si e télè, inu re á yó sí e pátápátá. Ife atunbo tèsíwájú. Okan ololufe re too fa si o nigbogbo igba. Omi kankan kole pana ife yin.

Do you want to make your boyfriend/girlfriend happy with some Yoruba love messages for him or her? Do you want to top up your love game and add spice to your romantic interest in Yoruba language? You desire your heartthrob to always think about you with a smile with your love messages? Perhaps, you want to dazzle him/her with sweet love sms in Yoruba but you’re shy with appropriate words?

Don’t go far! All you need to express your love to your darling boyfriend and girlfriend is right here. Check this out:

Nje iwo fe mu inu ololufe re dun ni 2024 pelu oro ifiranse ife awunilori? Nje iwo o fe ki ere ife yin nipon ju atehinwa lo? Abi o wu o ki eni bi okan re ma ranti re nigbogbo igba nipase oro ife to l’ágbára ti o ko ranse? Boya o ti le wun e pupo, sugbon o ko mo bi o se ma so? Ma lo jina! Gbogbo ohun ti o fe so lati seto sile ninu ogbon Ifiranse Ife Si Ololufe nisale yi. O da na, yèwóò:

Romantic Love messages in Yoruba Language

It’s time to enjoy your Yoruba love text messages with their interpretations in English, for better understanding. Your boyfriend, girlfriend, husband, wife and crush will enjoy every bit of these romantic love messages in Yoruba language – Òrò ìfìféhan ní èdè Yorùbá.

1. Ìfé okàn mi, ìwo ni eni bí okàn mi. Mo ni ife re lópòlopò, tó bèe gé ife re ti ta sími l’ópolo. L’éhìn re, kòsí èlòmíràn mo. Títí ayé ni mo mà f’ìfé hàn si e.

My Heartthrob, you are the one I love. I love you so much I feel intoxicated. You are all I have, no one else. I’ll love you forever.

2. Ololufemi, eyínfúnjowó, adúnmáradán. Èjíwùnmí mi àtàtà, eléyinjú egé, eni tí okàn mi ní ìfé sí Èkùró l’alábakú èwà. Títí ayé yoo fi paré ni ìfé èmi atì re.

My Love, the one with the perfect flashing white teeth, my black and beautiful one! Dimpled, lovely eyes, you are object of my affection. Where you are, is where I’ll be, inseparable. Our love is for eternity.

3. Adùn mi, mo feran re ju eyin ojú mi lo. Láìsí àní àní, iwo ni iyò ayé mi àti eyinju mi. Arewà obinrin mi, oniwa tútù bí àdàbà, olópolo tó péye. Èkùró l’alábákú èwà, kòsí ohun to le yàwá títí ayérayé. Mo bi ife re.

My Joy, you are the apple of my eyes. Without doubt, you’re the salt of my life, my very essence. My beautiful woman, gentle, brilliant and intelligent. Nothing shall ever separate us. I love you.

4. Arike temi nikan, o wun mi l’obinrin. Iwo ni adùnbáàrìn mi, òréke léwà omoge. Dajudaju, Olorun paapaa pari ise si o Lara, ko si alebu kan ninu èwà re no ti le wu ko kere to. Gbogbo ara ni mo fi feran re. Ko si ohun to le ya wa lailai.

My own beloved, you’re the desire of my heart. My perfect friend, companion and gist partner, beautiful inside and outside! You are God’s masterpiece, without a single flaw! I love you with the whole of my being. Nothing can ever separate us.

5. Arewa mi, ife re ma ndami lorun nigba gbogbo. Èwà re po, ko lafiwe. Èrín re ni idunnu mi. Ayò re, ni ifòkanbalè mi. Elerin eye, ma joba lo lookan ayà mi bóbá se wùn é. Mo bi ife re.

My Beauty, your love grips my heart without relenting. Your beauty is incomparable, and your cute smile thrills me. I find contentment in making you happy. The lady with the charming smile, you are the Queen of my heart. I adore you.

6. Idunnu mi, laisi Iwo, mi o mo bí aye mi yoo serí. Ìgbà gbogbo ni okàn mi ñfà si o gegebi eniyan to wa ninu aginjù nse àféèrí omi tó ñkán tororo. Mo feran re pupo.

My Joy, I can’t imagine life without you. My heart longs for you like a thirsty man in the desert longs for drop of water. I love you so much.

7. Awon eniyan ro wipe eniyan líle nimí; sugbon akikanju okunrin ti temi to ba foju gan an ni iwo ololufemi mi, níse mo mayó bii wara tótú sinu epo gbigbona. Mo ni ife re rékojá òsùpá padà.

People think I’m tough, but my toughness and bravado melts like butter at the sight of you, my Love. I love you to the moon and back.

8. Apónbéporé tèmi nìkan, níse ni ife re yókelé wo ookan àyà mi láìròtélè. Owó idà ife re ba mi títí o fi rápálá gba okàn ati gbogbo ara mi. Iwo l’emi mi, otutu ife re ràgàbòmí, àyàfi kí o fi ìfé re to gbona yo dànù. Mo bi ife re.

My fair-skinned dazzling beauty, your love crept on me unawares. Your Cupid arrow caught my heart till it took over my entire being. You’re my heartbeat, my heart yearns for you. Only the fire of your love sustains me. I love you.

9. Ojó ti mo pade re ni ìgbà òtun ti dé bámi. Ife ti mo ni si e, ife àîsètàn, ife to koja agbara mi. O nse mi bi ki nma fi ojojumo ri o, ki a si ma wa papoò lókoláyà. Mo ni ife re, Oyin mi.

My life turned around for good the day I met you. My overwhelming love for you is true, and without guile. I yearn to see you everyday of my life, to be together forever. I love you, Honey.

10. Orin ife ni mo ma njí ko ti okàn mi ba fa si e. Níse ni ero re ma ngba gbogbo okàn mi patapata. Agidi ni àti ‘je àti mu. Iwo ni atégún tí mo fi nmí. Iwo ni ayanfe mi. Mo ni ife re.

When I miss you, I wake up in the morning with a love song for you. I’m consumed with thoughts of you all day long. You’re the very breath that I take, you’re my beloved. I adore you.

Don’t forget that you can use these Yoruba love messages for any occasion. An example is birthday wishes in Yoruba language. All you need to do is copy the one your lover will appreciate and add happy birthday line in the end.

11. Mo ni ife re l’opolopo, arabinrin mi, ayanfe mi. Eyi je òtító pónbélé tí kò nílò àyèwò lati enu olólùfé re tí o ti otí ìfé yó bámúbámú.

I love you so much, my beloved woman. This is the whole verified truth, from your loved intoxicated dude!

12. Èmi kò ní ìdí kan pàtó ti mo fi feran re nigbagbogbo, tokàntokàn. Iwo ni eni bi okan mi, arewa ìwúrí mi, eni ti okàn mi n se àférí. Mo ni ife re gidigan.

I love you for no reason in all season. You are the love of my heart, my dream girl and my heartthrob. I love you so much.

13. Ife ti kíì s’étàn ni mo ni si e, Adufe mi owon gogo. Gbogbo nkan lo fi wùn mi. Ni ti ewà tó péye, o ò ní àfiwé. Ni ti opolopo ti won fi yangàn, ko si elégbé re. Oni ìwà ìrèlè, elérin èye, akoni obinrin ti ko se f’owo to s’éhìn. Mo feran e gidi gan, oni temi.

True love with no deceit is what I have for you, my darling. I love everything about you. Your beauty and brain are incomparable! You are gentle, charming and outstanding. Mine, I love you so much.

14. Idunnu aye mi, ojójúmó ni o ma nmu inu mi dun. Ayo mi si nma nkun nigba ku igba ti á ba jo wa pàpò. K’a ma pa iro, nko mo bo se ma nri lára mi ti nko ba gburo re lojumu ojo kan. Ife re ti ràgàbò mí.

My eternal Joy, you always make me happy. I’m always filled with joy when we are together. Truly, I’m always downcast anytime I don’t hear from you. I love you from the depth of my heart.

15. Iwo ni orisun ayo mi lóòrèkóòrè. Òdò re ni idunnu mi wa. Ife re l’okan aya mi dabi imole ti ogo e búyo jade bi oorùn. Mo ni ife re laini afiwe, arewa temi nikan.

You’re the indisputable source of my happiness. Your love is like the radiance of the sun. I love you without qualification, my beautiful one.

16. Mo gbiyanju lati se iwadi boya mo le din ife re ti npa mi bi oti ku, sugbon gbogbo igbiyanju mi, pato lo jasi. Kànràn ko san lara arakunrin re to ti yoofe, ise ni atégún ife re siji bomi. O wa n se mi bi ki nma ri o nigba gbogbo. Daju daju, ife àtokàn wa ni ife emi ati iwo. Titi aye ni irinajo ife wa. Mo ni ife re, òpékeléwà mi.

All my efforts to tune down the extent of my love for you, not only failed woefully, it boomeranged! I want to be with you everyday of my life. My love for you is eternal, I love you, my darling.

17. Òrò ìfé, bi àdánwò ni. Ko si ohun kohun to le paná ife re lokan aya mi. Èkùró lalabaku èwà, ko sohun to le ya wa. Je ka tesiwaju ninu irinajo ife ti ko labawon. Ibi ire lo ma jasi. Mo feran re, ó kojá àfénuso, Orente mi.

Love is a riddle no one can solve. My love for you is inextinguishable and forever. As we progress in this love adventure, Paradise is our goal. I love you so much, my sweetheart.

18. Awelewa temi nikan, o da mi loju wipe ojókójó ti n ko ba foju gan an ni re, tàbí gb’óhùn re lóri ago, ojo na lo ma gburo mi ni ile iwosan, níbi ti won ti nwo aisan pàjáwìrì. Ògbóntàrìgì egbògi kan sòso to le womisan ni ife re si mi. Angeli mi, mo feran re lati inu wa.

My Beautiful one, I’m certain that the day I don’t hear from you nor see you, I’d land at the emergency/intensive care unit at the hospital. Only one drug is potent enough to cure me: your love. I love you from the depth of my heart, my Angel.

Read: Do Bloggers Make Money from My Data?

19. Orekelewa mi, Dókítà ti jeri si ohun ti mo mo télè: ti mi o ba ti ti e tabi gbohun e, nkò le mí. Ife re ni atégún ti mo fi nmi. Iwo ni emi mi ati iyo aye mi. Titi lai ni ife mi si e.

My Sweetheart, the doctor just confirmed what I know for a fact: I cease to breathe if I don’t hear your voice. Your love is the breath of fresh air that I take. You are my heartbeat, my essence. I’ll love you till eternity.

20. Orente mi, mo feran re tokan tokan pelu ohun gbogbo ti mo ni laye lorun. Iwo ni ìsura mí. Ookan aya mi ni ife re wa l’ókàn mi.

My darling woman, my babe, I love you with the whole of my heart and everything I have. You are my treasure. I love you, wholeheartedly.

Yoruba Love Text Messages from Her to Him (Oro ife lati arabinrin si orekunrin tii se ololufe re:)

21. Ó ma nira lati se apejuwe to péye bi mo se ni’fe re to. Nje eniyan le gbe ile aye lai nilo afefe? Kò sése. Iwo ni afefe ti mo fi nmi. Mo feran lati ma wa pelu e ní gbogbo igba. Idunnu re ni ayo ti temi. Titi aye ni mo ma ko orin ife ti ko l’abawon si e, Ife mi.

It will be extremely difficult for me to explain how much I adore you. Can one live without breathing in air? Impossible! You are the air I breathe. Your happiness is my joy. I’ll sing a love song for you, forever. One without blemish, my Love.

22. Ololufemi owon gogo, eni bi okan mi, tí o bá ti di àsálé òní, mo fe ki o yojú lénu fèrèsé ìyàrá re. Wa sakiyesi irawo kan to da duro, to ntanna mònàmóná, èyí ti ògo rè búyo jáde. Èyí ìfé mi si e, tó ñsáná láì dáwò dúró. Mo ni ife re, akoni mi.

My darling lover, my heart delight, take a look out of your window in the cool of the night. You’ll see a lone star, blazing forth in all its glory. That’s my love for you, blazing forth without a pause. I love you, my champion.

23. Eyin ojú mi, akoni okùnrin ni é láàrín egbegbèrùn akínkanjú okùnrin. Iwo ni oba okàn re, títí ayé ni ijòba re l’ókan àya mi. Mo ni ife re títí ayé.

My knight in shining armour, you are the apple of my eyes. You’re exemplary amongst thousands of distinguished men. You’re the indisputable reigning king of my heart forever. I love you till eternity.

24. Arewà okùnrin mi, onítèmi àtàtà. Léhìn ìwo, kòsí elòmíràn. Títí lai ni èkùró ti tèmi se ma se alábákú èwà tìre. Gbogbo ibi tí ìgbín re bá fá de, ìkárahun tèmi ma tèlé e. A jo ma lo ìgbà yi pé pe pe. Mo ni ife re gidi gan.

My Handsome, my darling beloved! You are more than enough for me. Like a moth to a flame is our eternal affection. We’ll be together forever. I love you so much.

25. Onítèmi, ìwo ni ìmúse àlá mi. Gbogbo ohun to wun mi lara omokunrin lópé sí o lára. Nígbà míràn, ó ma ñdàbí pé mo nla àlá ni. Ìfé re dábì atégùn tí mo fí nmí. O dùn j’oyin lo. Mo ni ife re, ololufemi.

Mine, you’re my dream come true. You have everything I desire in a man, and then some more! It feels like a dream. Your love is like the air I breathe. You’re sweeter than honey, I love you my dearest!

27. Àrèmo okàn mi, bi mo ba se nri e ní okán mì á ma se gbìgbìgbì. Òdómokùnrin eléjè tútù, on’íwà pèlé. Iwo ni ìdí pàtàkì tí mo fi nrèrín. Iwo ni igi léhìn ogbà mi, apata ti ko je ki ìjì ìfé gbé mi subú. Titi aye ni ife mi si e.

Prince of my heart, my heart beats fast at the sight of you. You’re cool, calm and collected, a heady combination! You’re the reason behind my smiles, my staunch support and unshakable my rock. My love for you is forever.

28. Mo súre fún ojó tí mo pàdé e, arewa okunrin. Ololufemi àtàtà, gbogbo isesi re lo wú mi lóri. Èyí ni lati ran e létí wípé mo féràn re tokàn tokàn. Ñkankan ko le yi pàdà láyé l’órun.

I bless the day we met, Handsome. My darling heartthrob, I admire everything about you. This is to remind you that I love you from the depth of my heart. Nothing can change it.

29. Ayanfe mi, mo feran re típétípé. Ti mo ba ri o, inu mi a ma dùn, arà mi á yá gágá. Mo féràn re ju èmí mi lo. Ife re npa mí bí otí. Ó se ara mi gírí bí eni mu ‘kofí’. Ká má p’aró, mo fi yo’fé re bámúbámú.

My Heart desire, I love you so much. When I see you, I feel so happy and active with adrenaline rushing through my veins like some perked with coffee. I love you more than my life, I feel high on your love. Honestly? I’m high on your love.

30. Ife mi, ìwo ni ayanfe mi akoko. Ko s’elomiran léhìn ìwo. Ko jó rárá. Ti mo ba ni ànfàní lati yan ololufe míràn, Iwo ni eni ti okan mi yan. Ife re bo aso itiju kuro lorun mi, ó wò mi l’áso iyì. Ife re yo ibanuje kuro lokan mi, o bu ayo ti ko lopin sibe. Daju daju, iwo ni oba okan mi titi lailai. Mo ni ife re.

My love, you’re my heart’s first choice. No one comes even close. If I have to choose all over again, I’d still choose you as my man. Your love stripped me of shame and clothed me with honour. Your love removed sorrow from my heart and replaced it with eternal joy. Truly, you’re the king of my heart forever. I love you.

31. Erin re mu ayo wa si okan mi, o tu okan mi lara lojokojo. Mo ni ife re pupo, aya mi.

Your smile brings joy to my heart, it warms my heart every day. I love you so much, my wife.

32. Nigbati mo wa ninu aisan, ohun re mumi larada. Timoba ri ololufe mi, ife oju rẹ yoo fa mi sọdọ rẹ.

When I was sick, your voice healed me. Whenever I see your face, the love in your eyes attracts me towards you.

33. Nigba kugba ti mo ba ranti e, ọkan mi ma n kun ayo ati alaafia pipe.

Whenever I remember you, my heart fills with joy and perfect peace.

34. Mo fe wa pelu re ni gbogbo igba, mi o fe padanu re lailai. Iwo ni adun okan mi.

I am with you always, I don’t ever want to lose you. You’re my joy.

35. Ifamora re n yo okan mi, ifọwọkan rẹ n mu ọkan mi balẹ. Iwo ni ololufe mi ni tooto.

Your cuddles melt my heart, your touch gives peace to my mind. You’re truly my lover.

36. Bi irawo orun ti po to, be ni ife re ni okan mi. Mi o je fi e sere.

As many as the stars in the sky, so is your love in my heart. I dare not joke with you.

37. Mo se ileri fun o loni pe, mo ma se ohun ti oju ko riri lati ri erin ati idunnu re.

I promise you today, I will do what no eyes have seen just to see your smile and joy.

38. Leyin Olorun oba oke, iwo ni okan mi fe. Owo ree ni abo mi, aya re ni irọri mi. Ololufe mi, jowo fa mi mo ra.

After God – the king of heaven, you’re the one my heart chooses. Your hand covers me, your chest is my pillow. My love, pls draw me closer to you.

39. Iwo ni mo fe fi gogbo aye mi ba sere. Iwo ni mo fe koko ri ti moba ji loju orun. Iwo ni mo fẹ ri gbeyin ki mo to sun.

You’re the one I want to play with all my life. You’re the first person I want to see when I wake up. You’re the last person I want to see before I sleep.

40. Moo la ala loru ano, mo de rerin ni gba ti mo ji nitori pe o wa ni inu alaa mi. Koda, o wun mi lati tun ala na la loni. O tu okan mi lara.

I dreamt last night, and I laughed when I woke up because you were in my dreams. In fact, I wish to have that dream again today. It refreshes my soul.

41. Di mi mu, ki o si se ileri fun mi wipe, o o ni fi mi sile lojo ola. Iwo ni aye mi.

Hold my hands and promise me that you won’t leave me in the future. You’re my life.

42. Iwọ nikan ni moni ati ohun gbogbo ti mo le ni. Mi o ni padanu re loni, lola ati lojogbogbo.

You’re the only one I have and all I will ever have. I will not lose you today, tomorrow and always.

43. Moo nife ree – gbolohun ọrọ yi wa lati okan mi. Moo nife ree ni tooto, ololufe mi owon.

I love you – These words come from my heart. I truly love you, my dear.

44. Nigba ti o ba wa pelu mi, ohun gbogbo loni itumo. O mu itumo wa si aye mi.

When you are with me, everything is meaningful. You brought meaning to my life.

45. Imole aiye mi, ololufe okan mi, mo nife re loni ati titi dojo ale wa. Emi ko ni idojuti o lailai.

The light of my life, the lover of my heart, I love you today and till the end of our lives. I will never disappoint you.

46. Ololufe mi, mo n fi gbogbo ojo ro nu ni pa e, ife re wuwo lokan mi. Mi o le fi iseju kan gbagbe re.

My darling, I spend the whole day thinking about you, your love is heavy in my heart. I can’t forget you for a minute.

47. Iwo ni aye mi ati ola mi, layi si iwo, mi ori awon nkan woyii. Iwo ni oungbogo fun mi.

You are my life and my tomorrow, without you, I don’t see these things. You are my everything.

48. Oju re mole bi okuta iyebiye, awo ara re dan ju wura lo. O tan imole si aye mi.

Your face shines like a pearl, your skin is brighter than gold. You illuminated my life.

49. Iberu kan ti mo ni nipe, mi o fe wa laye yi lai si iwo nibe. O fi ayo kun aye mi.

The only fear I have is, I would not want to live in this world without you there. You add joy to my life.

50. Di Oro mi mu oloolufe mi, o je iyebiye nitori pe oti okan mi wa. Mo feran re pupo.

Hold on to my word, my love. It is precious because it comes from my heart. I love you so much.

51. Ní ṣe ni gbogbo iṣẹju ati àkókò nínú ọjọ dàbíi ìgbà tí a kọ́kọ́ pàdé. Bí mo bá wà pẹlú rẹ, ọkàn mi máa ń balẹ̀ gidi gan. Gbogbo nkán tí o má ń ṣe má ń mú kí ẹwà mi jáde dáadáa. Ìfẹ rẹ túbọ̀ ń pọ̀ síi ni ọkàn mi ni gbogbo ìgbà. Iwọ nìkan ni o tọ fún mi, tí o sì tún ń mú mi pé. Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ lónìí, l’óla àti ní ìgbà gbogbo.

Every moments of the day feels just like the very first time we met. Being around you makes me safe always. You bring out the goodness and beauty in me. I fall in love with you more over and again. You are the only one that was made for me and that makes everything perfect right now. I love you today, tomorrow and always.

52. Èrò kanṣoṣo tí ó máa ń wá sí ọkàn mi láti ìgbà tí mo ti pàdé rẹ ni wípé èmi àti ẹ, àyànmọ́ tí ó so wá pọ, ní agbára gan. Kò sí ohun tí mo fẹ ṣe nísìsiyìí ju kí n pariwo fún gbogbo aráyé wípé “Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ!”. Ìwọ nìkan ni ọmọba’binrin mi tí ó ṣe iyebíye jù lọ, ẹni bí ọkàn mi kan ṣoṣo.

A thought that has been constant in my heart since I met you is that we were made for each other. There’s nothing I want more than to scream “I love you” to the whole world. You are my charming princess, my one and only love.

53. Ohun kan tí ó dá mi lójú ni wípé, a má jọ wà papọ, kò sí bí ó ṣe lè jẹ́. Ìwọ nìkan ni o ni aṣẹ àti ẹtọ̀ sí mi, bẹ́ẹ̀sìni yóó ti rí. Kò sí ohun tí ó le yà wá nítorípé ìfẹ́ tí mo ní sí o ògidì ni, tí kò sí le yẹ́ láé.

One thing I am sure of is that we will always be together, no matter what at all. You’re the only one that has access to me and it will always remain so. Nothing will separate us because the love I have for you is real and long lasting.

54. A le ní àríyànjiyàn, ṣugbọn kò sí àyè fún ìjà àbí ìkùnsínú. Ìfẹ́ wa yóò yí, yóò sì dúró kò sí bí ìjì náà ṣe le tó. Mò dájú wípé kò ní sí ìpínyà tabi ọ̀nà tí ó jìn láàrin wa. Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ làti ìbẹ̀rẹ̀ mi, títí dé òpin.

We may argue and bicker at each other, but we will never have a fight. Our love will grow stronger and withstand any weather. Know that there will be nothing like distance between us. I love you from the beginning of me to the end.

55. Nítorí pé mo ní ọ, mo dá pé. Ìfẹ rẹ ń fi mi lọ́kàn balẹ̀ nígbàkígbà tí ayé bá fẹ yọ lẹ̀mìí mi. Ohun tí kò ní kò tíì ní ìrírí rẹ̀ rí ní ìfẹ́ rẹ ń ṣe fún mi, gbà mi gbọ tí mo bá sọ wípé ń kò fẹ́ kí’hun tó wà láàríín wa ó parí láyé.

With you, I am complete. Your love is my comfort whenever life comes at me with force. Your love does to me what I have never experienced and trust me when I say I don’t ever want this to end.

56. Ìfẹ́ òtítọ́ tí ó sì mọ́ gaara ni mo ní sí ọ. Ní ayé yìí, kò sí ohun tí mo ní lò ju, af’ìwọ. O tó fún mi, ní gbogbo ọ̀nà.

Love in it’s most true and most pure form is what I feel for you. In this life, there’s nothing more that I need, just you. You’re sufficient for me through and through.

57. Ohun kanṣoṣo tí ó wà ní orí mi ni gbogbo àsìkò nínú ọjọ ni ìfẹ́ mi sí ọ. Kí ní mo le jẹ́ bí n kò bá pàdé rẹ l’ayé? Mo dúpẹ́ pé o tọ̀ mí wá, o sì tún fún mi ní ìfẹ́ rẹ.

The only thing in my head every moment of the day is my love for you. What would I have been if I hadn’t met you? Thank you for coming to me and gifting me with your love.

58. Ní ayé yìí, ohun kan ló dájú, òhun sì ni wípé mo ní’fẹ̀ẹ́ rẹ tinutinu àti tọkàntọkàn. Ìpàdé èmi pẹlú rẹ wá láti òkè wá. Títí láé ni ngo ma ṣe àpónlé àti àyẹ́sí rẹ.

One thing is constant in this life and it is that I love you genuinely and sincerely. Meeting you was a divine chance and I will forever treasure you.

59. Bí ojú mi ṣe ń tàn rokoṣo nígbà tí o bá pé orúkọ mi kò ṣeé fi ṣe àkàwé bí ọkan mi ṣe má ń yọ. Ó máa ń jọ mí lójú bi ìfẹ ṣe lè rẹwa kí o sì dùn mọ mi tó báyìí. Ṣùgbọ́n náà, ngo níló ìdáhùn. Mo tí ní ọ, eléyìí sì ni o ṣe kókó jùlọ.

The sparkle in my eyes when you call my name is little compared to how my heart lits up. How can love be this beautiful? I have always wondered. But then, I don’t need an answer. I have you and that’s all that matters.

60. Láràárọ̀ kí iṣẹ́ tó múmú lọ́kàn mi, mo máa ń rán ara mi létí bí mo ṣe n’ifẹẹ́ rẹ̀ àti ohun tí o já mọ́ sí fún mi. Ìwọ ni ayé mi, títí láé.

Every morning before I get enmeshed in the days activities, I always remind myself of how much I love you and you mean to me. You are my world, forever.

61. Mi ò tilẹ̀ fẹ́ mọ ohunkóhun tí ó lè máa bọ̀ mọ́. Bí mo bá ṣá tí ní ọ lẹ́gbẹ̀ẹ́, mo lè kojú ohunkóhun. Ìwọ ní àlá mi ti ó wá sí ìmúṣẹ.

Whatever the world has in store, I don’t even care anymore. As long as I have you by my side, I can stand anything. You are my dream come true.

62. Ní gbogbo ìgbà, mo fẹ́ kí o máa rántí pé ìfẹ́ wa kò lè yẹ̀, mo ṣè’lérí bẹ́ẹ̀. Kò sí ohun tí yóò lè yà wá, láé. Mo n’ifẹẹ́ rẹ̀, pátápátá porogodo.

At all moment, always remember that this love has come to stay, I promise. Nothing will come between us ever. I love you, in totality.

63. Ìfẹ́ rẹ ni o máa ń mú mi l’ọ́kan le tí ó sì tún máa ń mú mi dúró ṣinṣin nígbà tí ọkàn mi bá fẹ máa dààmú. Títí láé ni ngo máa ṣe ọpẹ́ fún Ọlọ́run tí ó fi ọ́ fún mi gẹ́gẹ́bí ẹ̀bùn tí ó pé tí ayé mi nílò.

It is your love that holds me strong and keep me safe even when I am troubled. I will forever be grateful to God for giving you to me as my life’s perfect gift.

64. Ọ̀rẹ́ mi, ọ̀rẹ́minú mi, olólùfẹ́ mi, alábàáṣepọ̀ mi, olùdámọ̀ràn àti alátìlẹ́hìn ayé mi. Mo kàn fẹ́ sọ wípé ‘mo dúpẹ́ fún gbogbo ohun tí o jẹ́ fún mí’. Mo n’ifẹ̀ẹ́ rẹ júù bí ọ̀rọ̀ ẹnu lásán lọ.

You are my friend, best friend, lover, partner, confidant and life support. I just want to say thank you for being all this and more to me. I love you beyond words.

65. Ìdánilójú ńlá tí mo ní nínú ìfẹ́ tí o ní sími máa ń mú kí ọkàn mi sáré jù. Bí ìfẹ́ ògidì ṣe máa ń rí nì yìí. Ara àti ọkàn mi ti ṣe tán láti nífẹẹ rẹ laísì òdiwọ̀n kankan.

The assurance that I can always count on your love, makes my heart race wild. This is nothing short of true love. My body and mind is sold out to loving you without limitations.

66. Ayé mi yípadà ohun gbogbo sì rẹwà síi nígbà tí o dé inú rẹ̀. Mo ṣèlérí wípé tọkàn t’ẹ̀mí ni ngo fi dì ọ́ mú ṣinṣin nítorí pé, ó tọ́ sí ọ.

You came into my life and everything because just so beautiful. I promise that my heart and soul will hold onto you forever, you deserve it.

67. Ìfẹ rẹ jẹ́ ohun tí ó jẹ ohun tí ó rọrùn fún mi gbáà láti ṣe, kó dà, kò gba agídí rárá. Ìfẹ aláìlẹ́gbẹ́ ní eléyìí jẹ́. Ìwọ̀ ni àlà mi ti ó wá sí ìmúsẹ.

Loving you came so natural to me, loving you requires no effort, I guess that’s just one of the unique chemistry we have. You are my dream come true.

68. Inú mi dùn gidigidi wípé mo ṣe alábàápàdé rẹ, mo sì ṣubú sí ìfẹ́ rẹ. Ní gbólóhùn kan, mo kàn fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ wípé ìwọ ni ẹni náà tí ngo lo gbogbo ìgbésí ayé mi tí ó kù pẹ̀lú rẹ̀.

I’m glad I met you, knew you and fell in love with you. I just want to say thank you for being the one I get to spend the rest of my life with.

69. Mo kàn ní ìdánilójú wípé ìwọ ni alábàárìn tí ayé mi nílò. Ojoojúmọ́ pẹ̀lú rẹ máa ń mú ìrántí tí ó rẹwà gbáà dání. Ìwọ ni ohun tí ó dára jùlọ tí ó ṣẹlẹ̀ sí ayé mi.

I just knew you’re the most amazing companion that my life could use. Everyday with you is laced with beautiful memories. You are the best thing to happen to me.

70. Ẹwà rẹ dàbii ti angẹli, ó ń kọ mọ̀nà. Ẹ̀rín músẹ́ tí ó jáde láti ọkàn rẹ wá jẹ́ tí ẹwà tí ó mọ gaara láì ní àbàwọn kankan. Ayé mi àti ìṣúra mi ni o jẹ́. Mo nífẹẹ rẹ pẹ̀lú gbogbo nkán ti mo ni àti tí mo jẹ, jẹ́ kí eléyìí máa wà ní ọkàn rẹ ni gbogbo ìgbà.

Your beauty is as that of an angel, the smile from your heart a pure beauty. You are my life and my treasure, I love you with my all, never forget that.

71. Eni bi okan mi, ife re lo n’pa mi bi otin. Ninu okan re ni mo fe gbe bi ikun to gbe mi fun osu mesan. Be mi wo pelu ife re, iwo wo boya mi o ni fe e ju bi o ti ro lo. Titi lai lai ni okan mi ama gbongbe fun o.

My soulmate, your love intoxicates me. In your heart, I desire to dwell like the womb that carried me for nine months. Give me the benefit of the doubt of your love and see if I won’t love you beyond your imagination. Forever will my heart long after you.

72. Iwo ni eni keji mi, ibi ki bi to wu kin ma lo, mo ma gbe e da ni. Bi ojo se ma nro si ori ewe, beni ife mi a ma ro mo okan re titi de opin aye. Mo ma fi gbogbo ojo aye mi la ti fi ife mi han si e, lo tito, ati lo dodo.

You’re my better half, wherever I may go, you’ll go with me. Like the rain falls on leaves, so will my love rain on you forever. For the rest of my life, I’ll prove my love to you, in truth.

73. Aye gu do gbo nipa ife mi fun e, bi be ko, okan mi o ni ba le. Je kin fi e han si awon ebi mi, kan le fi oju kan obinrin to rewa ju bi won ti mo lo.

Until the world hears about my love for you, I’ll know no peace. Let me show you to my family, so they may see a beautiful woman they never knew.

74. Gbogbo nkan to dara la rare ati eyi to ku ka to ni mo ma komora. Mi o ni ju e nu nigbati ko da. Idunu re lo se koko se mi. Ife mi o ni ja e ku le bo ti wu ko ri.

I’ll embrace your good and bad sides. I’ll never let you go in trying times. Your joy is my utmost concern. My love, I’ll never relinquish you no matter the challenge.

75. Eyin oju re lewa bi ti okan osupa. Ina ife mi fun e a ma jo lo nigba ojo, ati nigba arun. Ma ja mi kule, fa mi mo ra bi ododo eye. Iwo ni mo fe fi aye mi fun, ayanfe mi.

Your eyes are as beautiful as the heart of the moon. The flame of my love will keep burning for you in good and bad times. Do not abandon me, draw me nearer like a dove. It’s you I want to give my life to, my love.

76. Aiye le ma reti eya wa, sugbon ofo ni won ma ba. Nitoripe, ife wa ju ogbon aye lo, ode ju imo oloye lo. Iwo sa fi ife kan ba mi lo. Wa de ri pe ife wa adun ju omi ti afi owuro pon. Ose ololufe mi.

The world may await our downfall, however, they’ll wait in vain. This is because, our love surpasses the wisdom of the universe and the understanding of the wise. Ultimately, you’ll see that our love is sweeter than the water fetched in the morning. Thank you, my love.

77. Adun mi, bi okin se daraju larin eye, be ni o se daraju gbogbo obinrin aye yi lo. Nje mo ti juwon e bi ife re se nse mi? Oro re ni kan ni mo riro lati aro da le. Je kin tan ju e ju bi obi re le ro lo.

My honey, like the peacock stands out amongst other birds, so are you amongst other women. Have I told you how your love makes me feel? I only think of you from dawn to dusk. Let me take care of you beyond your parent’s expectation.

78. Mo se leri fun e pe, ounje oba ni wa ma je ni ile mi. Aso olori ni wa ma wo ni sakani mi. O ni ba won je egungun, ode ni ba won wo akisa. Ileri mi ni fun e, orekelewa mi.

I promise you, that you’ll only eat the meals of kings in my abode. The apparel of queens shall you wear under my watch. You’ll not eat bones and neither shall you put on rags, my beauty.

79. Mo fe gbo ohun re nigba gbogbo. Nitori na, gba oruka ife mi fun e. Je kin fi ona roka nitori adun re. Je kin file poti nitori ewa re. Ife to dun ni mo ma fun e titi lailai.

I want to hear your voice at all time. So, take the ring of my love for you. I’ll throw a party for your beauty. Sweet love is what I’ll give you forever.

80. Ko si ife to rewa to titi wa. Okan re funfun ju oju orun lo. Irin ese re rewa ju ti eshin lo. Jo, fun mi ni aye lati fi ounje nu e ni gbogbo ojo aye re. Ife mi, ti o ba fi mi se eru, mo ma fi erin ati oyaya ma ba e lo.

There is no love as beautiful as ours. Your heart is whiter than the sky. Your steps are way beautiful than that of a horse. Kindly give me the grace to feed you for the rest of your life. If you make me your servant, with joy I’ll go with you.

81. Iwo ni idunu okan mi, nitori, ‘gba ti mori e, mo ri ohun to dun. Titi d’ola, iwo ni okan mi y’o ma fe, ara mi y’o fe di ro mo. Lagbara Oloun oba, ife wa ma wa titi lai.

You’re the joy of my heart. This is because when I saw you, I beheld a beauty thing. Till tomorrow, my heart will love you still and my body shall embrace you. By God’s grace, we’ll have everlasting love.

82. Ibi yo ba wu ti mo ba lo, iwo ni okan mi yo mafe lojojumo, irin ki rin ti miba rin, egbe re ni mo ma de si. Ni ojo oni, mo se ‘leri ife mi fun o, pe ama jo wa titi lailai.

No matter where I go, my heart will always love you. No matter the journey I make, I’ll take abode by your side. On this day, I promise you; we’ll be together forever.

83. Ololufemi, ma se ba mija. Ti oro ba sebi oro, jeka fi ife ati irele okan pari e. Mi o ni ba e je, la’i se pe mo ke e baje, nitori, mo feran e pupo. Ife mi fun e, loje kin ma sowi pe, mi o le gbe lai si wo.

My love, don’t be at loggerhead with me. When we disagree, let’s resolve our issues with love and humility. I will only treat you so kindly because I love you very much. My love for you makes me say, I can’t live without you.

84. Olo mi, dakun ma fe mi lo. Ayanfe mi, dakun ma da mi. Idunu mi, ma se komi si’le. Titi lai ni kajo ma gbe bi t’oko t’aya. Ife ako ja ofin ni k’eledua se tiwa.

My love, kindly love me forever. My chosen one, don’t betray me. My joy, do not abandon me. Forever, shall we live like husband and wife. May God grant us unconditional love.

85. Di mimu lowo, tele mi kalo, wo inu oju mi, kori inu okan mi bi moti fe e to. Jeki ife wa dawon lorun. Jeki erin wa se won lese. Ko si b’oba se leto laiye yi, iwo ni okan mi yo yonu si, ifemi.

Hold my hand, follow me, look into my eyes and see how much I love you in my heart. Let our love trouble them. Let our laughter hurt them. No matter how hard life gets, my heart will always melt when it comes to you, my love.

86. Ti mo ba ti ri oju re, okan mi man ba le. Ti mo ba gbo ohun re, idamu mi man ton. Ni oto, iwo ni eledua dafun mi. Nitorina, mi ‘ole fe imi, mi o dele wa pelu omiran.

When I see your eyes, I am at peace. When I hear your voice, my trouble vanishes. For this reason, I can’t love another and neither can I find another.

87. Obinrin bi wo ko pe meji laiye, okan bi ti e, sowon. Ife bi temi, iwo la da fun. Je kin fi ayo s’okan e. Je kin fi erin si oju e pelu ete mi. Ka di okan ninu aiye to kun fun opolopo eniyan. Iwo ni ma fe ni owuro ati ale mi.

You’re one of a kind woman, your heart is rare. Let me put joy in your heart. Let me put a smile on your face with my lips. Let’s become one in a crowded world. You’re the one I’ll love at the beginning and end of my life.

88. Iwo ni angeli ti mo ma kokori. Iwo ni irawo ti mo ma ko dimu. Gbogbo ojo aiye mi ni moma fi fe e laisi abamo. Titi di aiye ainipekun, ife wa adun joyin lo.

You’re the first angel I’ll ever see. You’re the first star I’ll ever hold. For the rest of my life will I love you without shortcoming. For everlasting, our love shall be sweeter than honey.

89. Gbo orin ti okan mi ko si e. Gbo oro ti enu mi so fun e. Orin ife, oro ife ti odun, ni okan mi ma so si e. Monife re, enibi okan mi.

Hear the song my heart sings for you. Hear the words my mouth speaks to you. Sweet words of love does my heart say to you. I love you, my soulmate.

90. Mo fe ba e lo, mo fe ba e gbe. Lododo, daju daju, iwo ni okan mi yan. Tori erin re ma so ibanuje mi dayo, bi ekun re se ma da okan mi lamu. Iwa re ni ewa mi.

I want to go with you. I want to live with you. This is because your laughter turns my sadness into joy just like your tears trouble my soul. Your beauty is my beauty.

91.Moja mosa laa mo akinkanju loju ogun, oro ife ki se oun adojuko lojiji. Iwo gan gan lo somi di akikanju ife. Titi lai, ni mo ma nife re!

Discretion is a better part of valour. U don’t just get caught in love, you made me champion of love. I will love you forever.

92. Ife re lokan mi dabi omi tutu inu amu, a mu ara mi ya gaga, amu are kuro lokan mi . Monife re, oro enu ko!

Your love in my heart is like the coolest water to me, it makes me strong and makes me hearty. I love you and it’s not only by mouth.

93. Iwo lejika tiko jeki ewu mi jabo, odami da oro ayemi. Tin ba wo iwaju, mori e, tin ba wo eyin owa nibe. Iwo ni ma feran titi ojo ayemi!

You are the shoulder that won’t allow my cloth to fall off, you didn’t leave me with my issues. When I look at the front, the back, all around, I see you. It’s you I will love till eternity.

94. Won sope ife wa pelu wahala ati ifooro, amo ibasepo emi ati e ko mi pe, ife lemu alaafia funni. Iwo ni orisun alaafia ati idunnu. Kini mashe tiko basi ife re laye mi. Monife re Aya mi.

They say love is with pain and troubles but our relationship taught me love can bring peace. You are the source of my peace and happiness. What will I do without your love in my life. I love you.

95. Oro agba ti ipade wa komi, nipe kin jawo ninu apon tio yo, kin gbomi’ila kana, egbin ati ibanuje ti oro ife ti da simi lara le pare ti moba gba lati woju ife lekan si. Odara ninu , osi tun dara lode!

The proverb that our meeting taught me is that,I should stop the old and try something new. The sadness that actions of love has brought to me can be wiped off if I look unto love again. You are beautiful in and out!

96. Mi oni fi igba kan bookan ninu, Pelu akoyawo ni ma fi ba elo. Elomiran oni gbo, ki o to gbo. Iwo leni akoko ni aye mi, aye re koni sofo lailai!

I won’t leave you out of my business, I will work with you with transparency. Nobody will know before you know, you are the first person in my life. Your place in my heart will never be empty.

97. Kin lo le fa ipinya larin wa , kin lo le fa idamu ti yo pinwa niya. Kosi nkan na ti yo mu mi manife ree nigba kugba. Owo re ni kokoro okan miwa!

What can cause separation between us, what can bring struggle to separate us. There is nothing that will stop me from loving you. You own the key to my heart.

98. Nibo nimo ma ti koba she Iwo, Iwo ni maapu ayemi. Ayemi nitumo, aye mi looju tori pe owa nibe nii! Mafi igba kankan komi sile, Iwo lokan mi wafun.

Where will I be if not with you, you are the map of my life. My life has direction, clarity because of your presence. Don’t ever leave me alone, my heart is meant for you.

99. Omu mi jade kuro ninu okunkun sinu Imole pelu ife loju e, mo nfi ojo ti mo pade e shadura lojo gbogbo tori ojo ayo ni. Mo ndupe lowo re tori pe onifemi.

You brought me out of darkness into light with love, I use the day we met to pray daily because it’s a day of joy. I’m thankful cos you love me.

100. Onitemi, Iwo ni ipinmi laye yi, ofi itumo si ewa mi . Oje kin deni akintan, Eni esin , ari pose. Ofi oyin saye mi, oshe fun gbogbo nkan toti she laye mi. Iwo nipin mi!

My very own, you are my inheritance in this life, you brought meaning to my beauty. You didn’t make me feel useless and used. You sweetened my life, thanks for everything you’ve done for me. You are my heritage!

101. Igbese kan timo rope ko ni kan mi , ni oro ife, amo oya mi lenu pe o gbe mi lo sodo ife, Ori mi bo inu e, o jeki di eni toni eyan nile. Mo ma nice titi ojo ayemi ni.

I thought love wouldn’t be my portion, but you took me to the river of love and dip me into the river of love. You made me someone who has a partner at home. I will love you till the end of time.

102. Oolo mi, Iwo ni mo ti nduro de lati le, Iwo ni alaabaro mi, Mafi igba kankan fimile.

My heartthrob, you are the person I’ve been waiting for all this while. You are my helper, don’t ever leave me for a second!

103. Olore mi, Iwo lofe rimi lojojumu, Iwo lalafisun mi. Eni to fimi she akoko ninu aye e! Ooto Simi, amo olorun fi e saanu mi ni. Monife re.

My helper, you are the person who wants to see me everyday, you are the one I report to. You made me first in my life. I don’t deserve you but God blessed me with you! I love you.

104. Olori laafin mi, ton ba ju abeebe sile nigbagba, ibi pelebe ni o fi leele, Iwo lo oma je ife okan mi, Iwo ni ma ma dele ba. Iwo nikan lowa fun mi.

My queen in my Palace, if we throw handfan 200 times, it’s still going to fall side ways. You are the only one who can be the love of my heart, you are the one I will come home to. You are the only one for me.

105. Ti won ba bimi pe kin tun enikeji mi mu, iwo na loma je. Iwo nikan lolorun sheda fun mi laye yi. Omu iyi wa pelu re, Omu iteriba wa pelu re, Omu ife wa pelu re, Omu ayo wa. Iwo loma je ife okan mi titi aye.

If they ask me to pick my partner all over again, you will still be the one. You brought value,, submission and love and joy. You are the love of my life forever.

106. Ti igbin ba fa, ikara hun ate le. Oro wa dabi oro igbin ati ikarahun e, eleda loso wapo, aye osi le yawa. Ifemi, leyin re, ko selo miran mo.

When snail moves, it moves with its shell. We are like snail and it’s shell, the creator made us just like that. Nobody can separate us, my love, after you there is no other person.

107. Ba ti waye pama ri laari, eleda ti ko emi ati e poo. Iwo ni ifemi, Ayomi, onitemi, oremi, ololufe mi, ayemi. Monife re!

We move according to fate and destiny, the creator made us for each other. You are my joy, my love, my own, my friend, my love, my life. I love you!

108. Bo oti wu ki sanmo fe to, okan lo osupa loju sanmo. Bo ti wu ki irawo poto, okan lo osupa. Iwo lo osupa timo ni, timo si tun ri boti wu, keniyan po to loju aye. Iwo lokan mife!

As big as the sky is, there is just one moon. As much as there are plenty stars, there is just one moon. You are the moon I see and have, even if the people on earth are like the sand of the sea. You are the one my heart chose.

109. Iwo leni bi okan mi, Iwo leni ti okan mi fe, Iwo lo momi, kosi enikeni, kosi nkan kan to le gbe ife re lokan mi. Bo ti wu, ki iji po to, Bo ti wu ki iji ja to, kosi nkan to le gbe ife okan mi lo.

You are the closest person to me, you are the one my heart choses, you are the one who knows me, no other one apart from you, nobody can take your love away from me. As much as the wind will whirl, nothing will take away my love.

120. Ekuro lalaba ku ewa, ajo ma gbo ni, ajo ma dagba nii. Iwo lejika mi, Iwo lewu mi, Iwo lejika mi, Iwo loni mi, Iwo lola mi. Ololufe mi, Monife re gidi gan ni.

We will grow old together. You are my shoulder, you are my cloth, you own me, you are my today and my future. My lover, I love you so much.

Read all?

Thanks so much for the privilege of being part of your love story and joy. It shall be endless love, full of joy without flaw by God’s grace.

E seun pupo fun anfani ti e fun mi lati le pin ninu ayo ife yin. Ife to lo yin to layo, ti ko ni abawon ni ife yin ma je l’ase edumare.

Hope you were able to pick a love message you found endearing for your love.

Feel free to drop your questions and comments on the Yoruba love text messages. Kindly share this with your friends, family and colleagues.

Thanks a lot.

Mo lero wipe e ri oro ife ti o mu ori wu ti e le firanse si ololufe. Ti e ba ni ibere, tabi e fe ni gbolohun ba mi so, e ni anfani lati ko si le.

Inu mi a dun lopolopo ti e ba le pin akori iwe yi pelu ore, ara ati ojulumo ti o le je anfani yi.

E se pupo.

Inspirational Birthday Wishes and Messages for My Sister

Inspirational Birthday Wishes and Messages for My Sister

Heart Touching Birthday Wishes for Wife

Heart Touching Birthday Wishes for Wife (2024)